Skip to content

AYẸYẸ ÀJỌ̀DÚN ỌBA FÁLÙÁDÉ ÀTI ỌDÚN AJÉ ÌLÚ ÌBÒGÙN

Gbogbo Ìgbìmọ̀ Ọ̀dọ́ Yorùbá Lágbàáyé fi ìdùnnú hàn sí Kábíèsí Aláyélúwà, Ọba FÁKÁYỌ̀DÉ Adéṣínà Fálùádé, Olú ti gbogbo Ilẹ̀ Ìbògùn Lápapọ̀

Ìgbìmọ̀ Ọ̀dọ́ Yorùbá Lágbàáyé Ẹ̀ka ti Ìpínlẹ̀ Ògùn lábẹ́ àkóso Ẹni-Ọ̀wọ̀ Sunday Adébọ̀wálé àti gbogbo àwọn Ìgbìmọ̀ yòókù ní Ìpínlẹ̀ Ògùn pẹ̀lú gbogbo Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ lápapọ̀, ni a fi tìdùnnú tayọ̀ kí Kábíèsí Ọba FÁLÙÁDÉ Fákáyọ̀dé Olú ti Ìlú Ìbògùn

A kí Kábíèsí kú Ayẹyẹ Ìwúyè Ìtẹ́ Ọba Ọdún Kẹrin tí wọ́n gun Orí Àpèrè Àwọn Baba ńlá wọn àti Ọdún Ajé Ìlú Ìbògùn

Àṣèyíṣàmọ́dún ooo

Káábíèsí Ọba Aláṣẹ Ìlú Ìlú Ìbògùn
Kádé ó pẹ́ lórí
Kí bàtà ó pẹ́ lẹ́sẹ̀
Kí àwọn Olorì ṣe iṣẹ́ ìbí pẹ́ láṣẹ Alálẹ̀
Kí ẹṣin Ọba ó jẹko pé o
Kí ìrùkẹ̀rẹ̀ ó dabẹ́rẹ́
Kí ẹ gbó
Kí ẹ tọ́
Kí ẹ dàgbà gbó bí Olú Ògbó
Tó gbó títí
Tó fi ọmọ owú ṣe ońdè sọ́rùn
Tí ọmọ owú jẹ kù bí abẹ́rẹ́
Abẹ́rẹ́ jẹ kù bí ìrù ẹṣin
Ìrù ẹṣin dìtí gàgàrà
Káááábíííèsí oo!!!

Yoruba nimi ọmọ karo o jire

Ìbuwọ́lù:

AsojuOdo (Hon) Sunday Adébọ̀wálé
Alága YCYW ti Ìpínlẹ̀ Ògùn

Aṣíwájú Ọlọ́kọ̀ Saheed
Akọ̀wé YCYW ti Ìpínlẹ̀ Ògùn
11/12/2021

Leave a Reply

Please log in using one of these methods to post your comment:

WordPress.com Logo

You are commenting using your WordPress.com account. Log Out /  Change )

Google photo

You are commenting using your Google account. Log Out /  Change )

Twitter picture

You are commenting using your Twitter account. Log Out /  Change )

Facebook photo

You are commenting using your Facebook account. Log Out /  Change )

Connecting to %s

%d bloggers like this: